Jeremiah 8:2-4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3 Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà
4 “Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀
wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí
ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,
kì í yí padà bí?
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.