Add parallel Print Page Options

21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú
    àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn baba
àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,
    àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”

22 Báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,
    a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde
    láti òpin ayé wá.
23 Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,
    Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú
wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n
    ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;
wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò
    jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”

Read full chapter