Isaiah 65:17-25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àwọn ọrun tuntun àti ayé tuntun
17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dá
àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun
A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,
tàbí kí wọn wá sí ọkàn.
18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé
nínú ohun tí èmi yóò dá,
nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú
àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.
19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu
n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;
ariwo ẹkún àti igbe
ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀
ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,
tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;
ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún
ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;
ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan
ni a ó pè ní ẹni ìfibú.
21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.
22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,
tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ,
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,
bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;
àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́
wọn fún ìgbà pípẹ́.
23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,
wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;
nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,
àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.
24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;
nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.
25 (A)Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,
kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,
ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.
Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”
ni Olúwa wí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.