Add parallel Print Page Options

(A)Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
    mú kí etí wọn kí ó wúwo,
    kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
    kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
    kí wọn kí ó má ba yípadà
    kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

Read full chapter

18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?

Read full chapter

39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé:

40 (A)“Ó ti fọ́ wọn lójú,
    Ó sì ti sé àyà wọn le;
kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
    kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
    kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

41 (B)Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

Read full chapter

26 (A)‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,
“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”
27 Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,
    etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,
    ojú wọn ni wọn sì ti di.
Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
    kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́,
    àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

Read full chapter