Isaiah 51:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbàlà ayérayé fún Sioni
51 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
Romu 10:2-3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. 3 (B)Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run.
Read full chapter
Romu 11:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Kí ha ni? Ohun tí Israẹli ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni àyànfẹ́ ti rí i, a sì sé àyà àwọn ìyókù le.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.