Add parallel Print Page Options

10 (A)Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
    má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.
Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.
    Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ
    ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;
àwọn tó ń bá ọ jà
    yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé.
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,
    ìwọ kì yóò rí wọn.
Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́
    yóò dàbí ohun tí kò sí.

Read full chapter