Isaiah 15-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu
15 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
Gbogbo orí ni a fá
gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
odò Poplari.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.
16 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
láti Sela, kọjá ní aginjù,
lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
2 Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
ní àwọn ìwọdò Arnoni.
3 “Fún wa ní ìmọ̀ràn
ṣe ìpinnu fún wa.
Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
ní ọ̀sán gangan.
Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han
4 Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”
Aninilára yóò wá sí òpin,
ìparun yóò dáwọ́ dúró;
òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
5 Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.
6 Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
7 Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
8 Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
9 Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale,
mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.
10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
òfo ni ó jásí.
13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”
Isaiah 25:10-12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí
ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
11 Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀
jáde láti lúwẹ̀ẹ́.
Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀
bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.
12 Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀
wọn yóò sì wà nílẹ̀
Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,
àní sí erùpẹ̀ lásán.
Esekiẹli 25:8-11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Moabu
8 (A)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,” 9 nítorí náà Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu. 10 Èmi yóò fi Moabu pẹ̀lú àwọn ará Ammoni lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ammoni láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; 11 Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí Moabu lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”
Read full chapter
Amosi 2:1-3
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí ó ti sun ún, di eérú,
egungun ọba Edomu
2 Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè
3 Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
Sefaniah 2:8-11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìlòdì sí Moabu àti Ammoni
8 (A)“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu,
àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni,
àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,
tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.
9 Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí,
“nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu
àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra,
ibi tí ó kún fún yèrèpè
àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.
Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;
àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni
yóò jogún ilẹ̀ wọn.”
10 Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,
nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà.
11 Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;
nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run.
Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,
olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.