Add parallel Print Page Options

20 Ṣùgbọ́n àwọn darandaran Gerari ń bá àwọn darandaran Isaaki jà sí kànga náà pé àwọn ni àwọn ni í. Nítorí náà ni ó fi pe orúkọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà sí kànga náà. 21 Àwọn ìránṣẹ́ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, wọ́n sì tún jà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sitna (kànga àtakò). 22 Ó sì tún kúrò níbẹ̀, ó sì gbẹ́ kànga mìíràn, wọn kò sì jásí èyí rárá, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nísinsin yìí, Olúwa ti fi ààyè gbà wá, a ó sì gbilẹ̀ si ní ilẹ̀ náà.”

Read full chapter