Gẹnẹsisi 17:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”
Read full chapter
Gẹnẹsisi 17:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ.
Read full chapter
Gẹnẹsisi 17:9-14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. 10 (A)Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. 11 (B)Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12 Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13 Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14 Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.”
Read full chapter
Gẹnẹsisi 17:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.