Add parallel Print Page Options

Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀

45 (A)Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.

Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀.

Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀síwájú fún ọdún márùn-ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú-ọmọ yín sí fún un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là.

“Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba (Olùdámọ̀ràn) fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. (B)Nísinsin yìí, ẹ yára padà sọ́dọ̀ baba mi kí ẹ sì wí fun un pé, èyí ni ohun tí Josẹfu ọmọ rẹ wí, Ọlọ́run ti fi mí ṣe olúwa fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, ẹ sọ̀kalẹ̀ wá láì jáfara. 10 Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní. 11 Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní.

12 “Ẹ̀yin fúnrayín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀. 13 Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”

14 Nígbà náà ni ó dì mọ́ Benjamini arákùnrin rẹ̀, ó sì sọkún, Benjamini náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú. 15 Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sọkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Josẹfu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀.

16 Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Farao pé àwọn arákùnrin Josẹfu dé, inú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn. 17 Farao wí fún Josẹfu pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kenaani, 18 kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’

19 “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá. 20 Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ”

21 Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú. 22 Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún ẹyọ owó (300) idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún. 23 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Ejibiti àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ. 24 Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”

25 Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani. 26 Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́. 27 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ. 28 Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

Joseph Makes Himself Known

45 Then Joseph could no longer control himself(A) before all his attendants, and he cried out, “Have everyone leave my presence!”(B) So there was no one with Joseph when he made himself known to his brothers. And he wept(C) so loudly that the Egyptians heard him, and Pharaoh’s household heard about it.(D)

Joseph said to his brothers, “I am Joseph! Is my father still living?”(E) But his brothers were not able to answer him,(F) because they were terrified at his presence.(G)

Then Joseph said to his brothers, “Come close to me.”(H) When they had done so, he said, “I am your brother Joseph, the one you sold into Egypt!(I) And now, do not be distressed(J) and do not be angry with yourselves for selling me here,(K) because it was to save lives that God sent me ahead of you.(L) For two years now there has been famine(M) in the land, and for the next five years there will be no plowing and reaping. But God sent me ahead of you to preserve for you a remnant(N) on earth and to save your lives by a great deliverance.[a](O)

“So then, it was not you who sent me here, but God.(P) He made me father(Q) to Pharaoh, lord of his entire household and ruler of all Egypt.(R) Now hurry(S) back to my father and say to him, ‘This is what your son Joseph says: God has made me lord of all Egypt. Come down to me; don’t delay.(T) 10 You shall live in the region of Goshen(U) and be near me—you, your children and grandchildren, your flocks and herds, and all you have.(V) 11 I will provide for you there,(W) because five years of famine(X) are still to come. Otherwise you and your household and all who belong to you will become destitute.’(Y)

12 “You can see for yourselves, and so can my brother Benjamin,(Z) that it is really I who am speaking to you.(AA) 13 Tell my father about all the honor accorded me in Egypt(AB) and about everything you have seen. And bring my father down here quickly.(AC)

14 Then he threw his arms around his brother Benjamin and wept, and Benjamin(AD) embraced him,(AE) weeping. 15 And he kissed(AF) all his brothers and wept over them.(AG) Afterward his brothers talked with him.(AH)

16 When the news reached Pharaoh’s palace that Joseph’s brothers had come,(AI) Pharaoh and all his officials(AJ) were pleased.(AK) 17 Pharaoh said to Joseph, “Tell your brothers, ‘Do this: Load your animals(AL) and return to the land of Canaan,(AM) 18 and bring your father and your families back to me. I will give you the best of the land of Egypt(AN) and you can enjoy the fat of the land.’(AO)

19 “You are also directed to tell them, ‘Do this: Take some carts(AP) from Egypt for your children and your wives, and get your father and come. 20 Never mind about your belongings,(AQ) because the best of all Egypt(AR) will be yours.’”

21 So the sons of Israel did this. Joseph gave them carts,(AS) as Pharaoh had commanded, and he also gave them provisions for their journey.(AT) 22 To each of them he gave new clothing,(AU) but to Benjamin he gave three hundred shekels[b] of silver and five sets of clothes.(AV) 23 And this is what he sent to his father: ten donkeys(AW) loaded with the best things(AX) of Egypt, and ten female donkeys loaded with grain and bread and other provisions for his journey.(AY) 24 Then he sent his brothers away, and as they were leaving he said to them, “Don’t quarrel on the way!”(AZ)

25 So they went up out of Egypt(BA) and came to their father Jacob in the land of Canaan.(BB) 26 They told him, “Joseph is still alive! In fact, he is ruler of all Egypt.”(BC) Jacob was stunned; he did not believe them.(BD) 27 But when they told him everything Joseph had said to them, and when he saw the carts(BE) Joseph had sent to carry him back, the spirit of their father Jacob revived. 28 And Israel said, “I’m convinced!(BF) My son Joseph is still alive. I will go and see him before I die.”(BG)

Footnotes

  1. Genesis 45:7 Or save you as a great band of survivors
  2. Genesis 45:22 That is, about 7 1/2 pounds or about 3.5 kilograms