Add parallel Print Page Options

Ìṣubú ènìyàn

(A)Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

Read full chapter

14 (A)Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,

“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn
    àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!
Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,
    ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
    ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
15 (B)Èmi yóò sì fi ọ̀tá
    sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,
    àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;
òun yóò fọ́ orí rẹ,
    ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

Read full chapter

Aṣọ mímọ́ fún olórí àlùfáà

Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.

Read full chapter