Add parallel Print Page Options

10 Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.”

12 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.

Read full chapter