Esekiẹli 20:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ààmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.
Read full chapter
Esekiẹli 21:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Kí ọkàn kí ó lè yọ́
kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,
mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun
Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,
a gbá a mú fún ìparun.
Esekiẹli 21:17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́
ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀
Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
Lefitiku 20:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀.
Read full chapter
Deuteronomi 5:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)(B) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
Deuteronomi 27:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.