Add parallel Print Page Options

18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 (A)Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

Read full chapter