Eksodu 30:13-15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa. 14 Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa. 15 Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.