Add parallel Print Page Options

Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,

Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

(A)Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi.

Read full chapter