2 Samuẹli 3:2-5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni:
Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un.
3 Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un;
ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.
4 Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;
àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali;
5 Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un.
Wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni.
2 Samuẹli 5:14-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Èyí sì ni orúkọ àwọn tí a bí fún un ní Jerusalẹmu; Ṣammua, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. 15 Àti Ibhari, àti Eliṣua, àti Nefegi, àti Jafia. 16 Àti Eliṣama, àti Eliada, àti Elifeleti.
Read full chapter
1 Kronika 14:3-6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin. 4 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni, 5 Ibhari, Eliṣua, Elifeleti, 6 Noga, Nefegi, Jafia,
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.