2 Samuẹli 20:23-26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi
23 (A)Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli;
Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.
24 Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde;
Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.
25 Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé;
Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.
26 Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.
1 Kronika 18:14-17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Àwọn oníṣẹ́ Dafidi
14 (A)Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun;
Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;
16 Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà;
Safsa jẹ́ akọ̀wé;
17 Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti;
àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.