2 Kronika 36:5-8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jehoiakimu ọba Juda
5 (A)Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. 6 Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli. 7 Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé Olúwa lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli.
8 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.