Add parallel Print Page Options

Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi

23 (A)Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli;

Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.

24 Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde;

Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.

25 Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé;

Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.

26 Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.

Read full chapter

Àwọn oníṣẹ́ Dafidi

14 (A)Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun;

Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16 Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà;

Safsa jẹ́ akọ̀wé;

17 Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti;

àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.

Read full chapter