2 Ọba 22:3-7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Ní ọdún kejì-dínlógún tí ó fi jẹ ọba. Ọba Josiah rán akọ̀wé, Ṣafani ọmọ Asalia, ọmọ Meṣullamu, sí ilé Olúwa. Ó wí pé; 4 “Gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, kí o sì jẹ́ kí ó ṣírò iye owó tí a mú wá sí ilé Olúwa, tí àwọn olùṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn. 5 Ẹ sì jẹ́ kí wọn ó fi lé àwọn ọkùnrin tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé Olúwa. Kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn ọkùnrin san án fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń tún ilé Olúwa ṣe. 6 Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn akọ́lé. Bákan náà ni wọ́n ra igi àti òkúta ọlọ́ṣọ̀ọ́ láti fi tún tẹmpili ṣe. 7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní láti ṣe ìṣirò fún owó náà tí a fi fún wọn, nítorí wọ́n ṣe òtítọ́.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.