Add parallel Print Page Options

25 Jẹ ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá ń tà lọ́jà. Má ṣe gbìyànjú láti wádìí lọ́wọ́ ẹni tí ń tà á nítorí ẹ̀rí ọkàn. 26 (A)Nítorí “Ayé àti gbogbo nǹkan rere tí ń bẹ nínú rẹ̀, tí Olúwa ni wọ́n jẹ́.”

27 Bí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ba pè yín sí ibi àsè láti jẹun, bá a lọ. Gba ìpè rẹ̀ tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Jẹ ohunkóhun tí ó bá pèsè sílẹ̀ fún àsè náà, má ṣe béèrè ohunkóhun nípa rẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn.

Read full chapter

14 Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún.

Read full chapter

15 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ohun gbogbo ló jẹ́ mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn tó ti díbàjẹ́ tí wọ́n kò sí ka ohunkóhun sí mímọ́. Nítòótọ́, àti ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ló ti díbàjẹ́.

Read full chapter

15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

Read full chapter