Add parallel Print Page Options

Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín: ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. (A)Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. (B)Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀: kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10 Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

Read full chapter

Ìfẹ́ Ọlọ́run àti ti àwa

(A)Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa: nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àti gbogbo ẹni tí ó bá ní ìfẹ́, a bí i nípa ti Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.

Read full chapter