Add parallel Print Page Options

16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 17 (A)Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18 (B)Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (C)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (D)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (E)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.

Read full chapter