Add parallel Print Page Options

23 (A)Ó sì ṣe agbádá dídá, ó ṣe bíríkítí, ó wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé èkejì àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga rẹ̀. Ó sì gba okùn ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ láti wọ́n yí i ká. 24 Ní ìsàlẹ̀ etí rẹ̀, kókó wá yí i ká, mẹ́wàá nínú ìgbọ̀nwọ́ kan. Ó yí agbádá náà káàkiri, a dá kókó náà ní ọ̀wọ́ méjì, nígbà tí a dá a.

25 Ó sì dúró lórí màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta sì kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù, mẹ́ta sì kọjú sí ìlà-oòrùn. Agbada náà sì jókòó lórí wọn, gbogbo apá ẹ̀yìn wọn sì ń bẹ nínú. 26 Ó sì nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ago, bí ìtànná lílì. Ó sì gba ẹgbàá (2,000) ìwọ̀n bati.

Read full chapter