Òwe 13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí.
2 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere
ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá.
3 Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun.
4 Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,
ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
5 Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́
Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.
6 Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,
ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.
7 Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan
ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
8 Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀
ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
9 Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,
ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú.
10 Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni
ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.
11 Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.
12 Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀
ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.
13 Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.
14 Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.
15 Òye pípé ń mú ni rí ojúrere
Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́.
16 Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀
Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
17 Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú
ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá.
18 Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.
19 Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn
ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.
20 Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n
ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.
21 Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,
ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.
22 Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
23 Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá
ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.
24 Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.
25 Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn
ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.