Add parallel Print Page Options

14 A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

15 (A)Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; 16 (B)Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà:

Read full chapter