Add parallel Print Page Options

(A)Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:

“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’
    kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
    kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.
(B)Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,
    Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.
(C)San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,
    kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
    Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.

Read full chapter