Romu 4:18-20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 (A)Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” 19 (B)Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara: 20 Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run;
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.