Romu 4:11-13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 (A)Ó sì gbé ààmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12 Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.
13 (B)Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.