Nehemiah 13:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.
Read full chapter
Jeremiah 17:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
21 Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu.
Read full chapter
Johanu 7:23
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
23 (A)Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi?
Read full chapter
Johanu 9:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisi wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”
Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàrín wọn.
Read full chapter
Marku 2:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 Díẹ̀ nínú àwọn Farisi wí fún Jesu pé, “Wò ó, èéṣe tiwọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.