Add parallel Print Page Options

35 (A)Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé:

“Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀.
    Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”

Àlàyé òwe èpò àti alikama

36 Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”

37 Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere.

Read full chapter