Marku 10:29-31
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, 30 (A)tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31 (B)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.