Johanu 2:1-11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu sọ omi di ọtí wáìnì
2 (A)Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀, 2 A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà. 3 (B)Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”
4 (C)Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”
5 Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”
6 (D)Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.
7 Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.
8 Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.”
Wọ́n sì gbé e lọ; 9 alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan, 10 Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”
11 (E)Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ ààmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.
Read full chapter
Matiu 8:5-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìgbàgbọ́ balógun ọ̀rún
5 (A)Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. 6 O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”
7 Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”
8 Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 9 Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
10 Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí.
Read full chapter
Luku 7:2-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. 3 Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. 4 Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún: 5 (A)Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” 6 Jesu sì ń bá wọn lọ.
Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi: 7 Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 8 Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
9 Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” 10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.