Jobu 9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jobu Fún Bilidadi lésì Nípa Ẹ̀kọ́ àti ẹ̀rí Ìdájọ́ Ọlọ́run
9 Jobu sì dáhùn ó sì wí pé:
2 “Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́.
Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3 Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà,
òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún ọ̀rọ̀.
4 Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun;
ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5 Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́:
tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.
6 Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀,
ọwọ́n rẹ̀ sì mì tìtì.
7 Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn,
kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
8 Òun nìkan ṣoṣo ni ó ta ojú ọ̀run,
ti ó sì ń rìn lórí ìgbì Òkun.
9 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari, Orioni
àti Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
10 Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ,
àní ohun ìyanu láìní iye.
11 Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i,
ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12 Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?
Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13 Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,
àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
14 “Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé?
Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí?
15 Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn;
ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16 Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn,
èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17 Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá,
ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí.
18 Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi,
ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19 Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó!
Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20 Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi;
bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
21 “Olóòótọ́ ni mo ṣe,
síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi,
ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22 Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:
‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23 Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,
yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
24 Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;
ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;
bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,
wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26 Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;
bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27 Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,
èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28 Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,
èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29 Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,
ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30 Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi,
tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31 síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò
ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32 “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,
tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa
tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34 Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,
kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí
35 Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀;
ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.
Job 9
King James Version
9 Then Job answered and said,
2 I know it is so of a truth: but how should man be just with God?
3 If he will contend with him, he cannot answer him one of a thousand.
4 He is wise in heart, and mighty in strength: who hath hardened himself against him, and hath prospered?
5 Which removeth the mountains, and they know not: which overturneth them in his anger.
6 Which shaketh the earth out of her place, and the pillars thereof tremble.
7 Which commandeth the sun, and it riseth not; and sealeth up the stars.
8 Which alone spreadeth out the heavens, and treadeth upon the waves of the sea.
9 Which maketh Arcturus, Orion, and Pleiades, and the chambers of the south.
10 Which doeth great things past finding out; yea, and wonders without number.
11 Lo, he goeth by me, and I see him not: he passeth on also, but I perceive him not.
12 Behold, he taketh away, who can hinder him? who will say unto him, What doest thou?
13 If God will not withdraw his anger, the proud helpers do stoop under him.
14 How much less shall I answer him, and choose out my words to reason with him?
15 Whom, though I were righteous, yet would I not answer, but I would make supplication to my judge.
16 If I had called, and he had answered me; yet would I not believe that he had hearkened unto my voice.
17 For he breaketh me with a tempest, and multiplieth my wounds without cause.
18 He will not suffer me to take my breath, but filleth me with bitterness.
19 If I speak of strength, lo, he is strong: and if of judgment, who shall set me a time to plead?
20 If I justify myself, mine own mouth shall condemn me: if I say, I am perfect, it shall also prove me perverse.
21 Though I were perfect, yet would I not know my soul: I would despise my life.
22 This is one thing, therefore I said it, He destroyeth the perfect and the wicked.
23 If the scourge slay suddenly, he will laugh at the trial of the innocent.
24 The earth is given into the hand of the wicked: he covereth the faces of the judges thereof; if not, where, and who is he?
25 Now my days are swifter than a post: they flee away, they see no good.
26 They are passed away as the swift ships: as the eagle that hasteth to the prey.
27 If I say, I will forget my complaint, I will leave off my heaviness, and comfort myself:
28 I am afraid of all my sorrows, I know that thou wilt not hold me innocent.
29 If I be wicked, why then labour I in vain?
30 If I wash myself with snow water, and make my hands never so clean;
31 Yet shalt thou plunge me in the ditch, and mine own clothes shall abhor me.
32 For he is not a man, as I am, that I should answer him, and we should come together in judgment.
33 Neither is there any daysman betwixt us, that might lay his hand upon us both.
34 Let him take his rod away from me, and let not his fear terrify me:
35 Then would I speak, and not fear him; but it is not so with me.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.