Add parallel Print Page Options

12 Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

13 Kí ẹnikẹ́ni tí a dánwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò; 14 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ.

Read full chapter