Isaiah 55:1-2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ
55 (A)“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
ẹ wá sí ibi omi;
àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
láìsí owó àti láìdíyelé.
2 Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
Johanu 4:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 (A)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”
Read full chapter
Johanu 6:48-51
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
48 Èmi ni oúnjẹ ìyè. 49 Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. 50 Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.