Add parallel Print Page Options

Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn
    mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;
    Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

“Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
    jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
    jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
    Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

(A)“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
    ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
    ‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
    ‘Òun kò ní ọwọ́?’

Read full chapter