Add parallel Print Page Options

13 Hamani sì sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀ àti ìyàwó o rẹ̀ sọ fún un pé, “Níwọ́n ìgbà tí Mordekai ti jẹ́ ẹ̀yà Júù, níwájú ẹni tí ìṣubú rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀, ìwọ kò lè rí ẹ̀yìn in rẹ̀—dájúdájú ìwọ yóò parun!” 14 Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀, àwọn ìwẹ̀fà ọba wọlé, wọ́n sì kán Hamani lójú láti lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè.

Read full chapter