Esekiẹli 16:4
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
4 Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fi omi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi aṣọ wé ọ.
Read full chapter
Esekiẹli 16:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 “ ‘Ṣùgbọ́n, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, ìwọ sì di alágbèrè nítorí òkìkí rẹ. Ìwọ sì fọ́n ojúrere rẹ káàkiri sí orí ẹni yówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ.
Read full chapter
Numeri 11:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.
Read full chapter
Nehemiah 9:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè.
Read full chapter
Saamu 78:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 (A)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
Saamu 105:40
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.