Add parallel Print Page Options

Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà. Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, àti aṣọ ìgúnwà efodu, àti efodu, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu dì í.

Read full chapter