2 Samuẹli 12:8-10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. 9 Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.