Luku 22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Judasi gbà láti da Jesu
22 (A)Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́. 2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn. 3 Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. 4 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. 5 (B)Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. 6 Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
7 (C)(D) Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ. 8 (E)Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ.”
9 Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
10 Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀, 11 kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 12 Òun ó sì fi gbàngàn ńlá kan lókè ilé hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”
13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
14 (F)Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀. 15 (G)Ó sì wí fún wọn pé, “Tinútinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà: 16 (H)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”
17 (I)Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrín ara yín. 18 (J)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”
19 (K)Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé, “Èyí ni ara mí tí a fi fún yín: ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”
20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín. 21 (L)Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì. 22 Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.” 23 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè láàrín ara wọn, ta ni nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.
24 (M)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (N)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (O)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (P)(Q)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (R)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (S)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”
31 (T)Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: 32 (U)Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”
33 (V)Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”
34 Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”
35 (W)Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”
Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”
36 (X)Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò-owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ọ̀kan. 37 (Y)Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”
38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”
Jesu gbàdúrà lórí òkè olifi
39 (Z)Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 40 (AA)(AB)Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.” 41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42 (AC)Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43 Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.
45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”
Wọ́n mú Jesu
47 (AD)Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 48 Jesu sì wí fún un pé, “Judasi, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”
49 (AE)Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?” 50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.
51 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé, “Ko gbọdọ̀ ṣe èyí mọ.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.
52 Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá? 53 (AF)Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò tiyín ni èyí, àti agbára òkùnkùn n jẹ ọba.”
Peteru sẹ́ Jesu
54 (AG)Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 (AH)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”
Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”
59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”
60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (AI)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ n gan Jesu
63 (AJ)Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
Jesu níwájú Pilatu àti Herodu
66 (AK)Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67 (AL)“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”
Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́; 68 Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ). 69 Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”
70 (AM)Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”
71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”
Luke 22
New King James Version
The Plot to Kill Jesus(A)
22 Now (B)the Feast of Unleavened Bread drew near, which is called Passover. 2 And (C)the chief priests and the scribes sought how they might kill Him, for they feared the people.
3 (D)Then Satan entered Judas, surnamed Iscariot, who was numbered among the (E)twelve. 4 So he went his way and conferred with the chief priests and captains, how he might betray Him to them. 5 And they were glad, and (F)agreed to give him money. 6 So he promised and sought opportunity to (G)betray Him to them in the absence of the multitude.
Jesus and His Disciples Prepare the Passover
7 (H)Then came the Day of Unleavened Bread, when the Passover must be [a]killed. 8 And He sent Peter and John, saying, “Go and prepare the Passover for us, that we may eat.”
9 So they said to Him, “Where do You want us to prepare?”
10 And He said to them, “Behold, when you have entered the city, a man will meet you carrying a pitcher of water; follow him into the house which he enters. 11 Then you shall say to the master of the house, ‘The Teacher says to you, “Where is the guest room where I may eat the Passover with My disciples?” ’ 12 Then he will show you a large, furnished upper room; there make ready.”
13 So they went and (I)found it just as He had said to them, and they prepared the Passover.
Jesus Institutes the Lord’s Supper
14 (J)When the hour had come, He sat down, and the [b]twelve apostles with Him. 15 Then He said to them, “With fervent desire I have desired to eat this Passover with you before I suffer; 16 for I say to you, I will no longer eat of it (K)until it is fulfilled in the kingdom of God.”
17 Then He took the cup, and gave thanks, and said, “Take this and divide it among yourselves; 18 for (L)I say to you, [c]I will not drink of the fruit of the vine until the kingdom of God comes.”
19 (M)And He took bread, gave thanks and broke it, and gave it to them, saying, “This is My (N)body which is given for you; (O)do this in remembrance of Me.”
20 Likewise He also took the cup after supper, saying, (P)“This cup is the new covenant in My blood, which is shed for you. 21 (Q)But behold, the hand of My betrayer is with Me on the table. 22 (R)And truly the Son of Man goes (S)as it has been determined, but woe to that man by whom He is betrayed!”
23 (T)Then they began to question among themselves, which of them it was who would do this thing.
The Disciples Argue About Greatness
24 (U)Now there was also a dispute among them, as to which of them should be considered the greatest. 25 (V)And He said to them, “The kings of the Gentiles exercise lordship over them, and those who exercise authority over them are called ‘benefactors.’ 26 (W)But not so among you; on the contrary, (X)he who is greatest among you, let him be as the younger, and he who governs as he who serves. 27 (Y)For who is greater, he who sits at the table, or he who serves? Is it not he who sits at the table? Yet (Z)I am among you as the One who serves.
28 “But you are those who have continued with Me in (AA)My trials. 29 And (AB)I bestow upon you a kingdom, just as My Father bestowed one upon Me, 30 that (AC)you may eat and drink at My table in My kingdom, (AD)and sit on thrones judging the twelve tribes of Israel.”
Jesus Predicts Peter’s Denial(AE)
31 [d]And the Lord said, “Simon, Simon! Indeed, (AF)Satan has asked for you, that he may (AG)sift you as wheat. 32 But (AH)I have prayed for you, that your faith should not fail; and when you have returned to Me, (AI)strengthen your brethren.”
33 But he said to Him, “Lord, I am ready to go with You, both to prison and to death.”
34 (AJ)Then He said, “I tell you, Peter, the rooster shall not crow this day before you will deny three times that you know Me.”
Supplies for the Road
35 (AK)And He said to them, “When I sent you without money bag, knapsack, and sandals, did you lack anything?”
So they said, “Nothing.”
36 Then He said to them, “But now, he who has a money bag, let him take it, and likewise a knapsack; and he who has no sword, let him sell his garment and buy one. 37 For I say to you that this which is written must still be [e]accomplished in Me: (AL)‘And He was numbered with the transgressors.’ For the things concerning Me have an end.”
38 So they said, “Lord, look, here are two swords.”
And He said to them, “It is enough.”
The Prayer in the Garden(AM)
39 (AN)Coming out, (AO)He went to the Mount of Olives, as He was accustomed, and His disciples also followed Him. 40 (AP)When He came to the place, He said to them, “Pray that you may not enter into temptation.”
41 (AQ)And He was withdrawn from them about a stone’s throw, and He knelt down and prayed, 42 saying, “Father, if it is Your will, take this cup away from Me; nevertheless (AR)not My will, but Yours, be done.” 43 [f]Then (AS)an angel appeared to Him from heaven, strengthening Him. 44 (AT)And being in agony, He prayed more earnestly. Then His sweat became like great drops of blood falling down to the ground.
45 When He rose up from prayer, and had come to His disciples, He found them sleeping from sorrow. 46 Then He said to them, “Why (AU)do you sleep? Rise and (AV)pray, lest you enter into temptation.”
Betrayal and Arrest in Gethsemane(AW)
47 And while He was still speaking, (AX)behold, a multitude; and he who was called (AY)Judas, one of the twelve, went before them and drew near to Jesus to kiss Him. 48 But Jesus said to him, “Judas, are you betraying the Son of Man with a (AZ)kiss?”
49 When those around Him saw what was going to happen, they said to Him, “Lord, shall we strike with the sword?” 50 And (BA)one of them struck the servant of the high priest and cut off his right ear.
51 But Jesus answered and said, “Permit even this.” And He touched his ear and healed him.
52 (BB)Then Jesus said to the chief priests, captains of the temple, and the elders who had come to Him, “Have you come out, as against a (BC)robber, with swords and clubs? 53 When I was with you daily in the (BD)temple, you did not try to seize Me. But this is your (BE)hour, and the power of darkness.”
Peter Denies Jesus, and Weeps Bitterly(BF)
54 (BG)Having arrested Him, they led Him and brought Him into the high priest’s house. (BH)But Peter followed at a distance. 55 (BI)Now when they had kindled a fire in the midst of the courtyard and sat down together, Peter sat among them. 56 And a certain servant girl, seeing him as he sat by the fire, looked intently at him and said, “This man was also with Him.”
57 But he denied [g]Him, saying, “Woman, I do not know Him.”
58 (BJ)And after a little while another saw him and said, “You also are of them.”
But Peter said, “Man, I am not!”
59 (BK)Then after about an hour had passed, another confidently affirmed, saying, “Surely this fellow also was with Him, for he is a (BL)Galilean.”
60 But Peter said, “Man, I do not know what you are saying!”
Immediately, while he was still speaking, [h]the rooster crowed. 61 And the Lord turned and looked at Peter. Then (BM)Peter remembered the word of the Lord, how He had said to him, (BN)“Before the rooster [i]crows, you will deny Me three times.” 62 So Peter went out and wept bitterly.
Jesus Mocked and Beaten(BO)
63 (BP)Now the men who held Jesus mocked Him and (BQ)beat Him. 64 [j]And having blindfolded Him, they (BR)struck Him on the face and asked Him, saying, “Prophesy! Who is the one who struck You?” 65 And many other things they blasphemously spoke against Him.
Jesus Faces the Sanhedrin(BS)
66 (BT)As soon as it was day, (BU)the elders of the people, both chief priests and scribes, came together and led Him into their council, saying, 67 (BV)“If You are the Christ, tell us.”
But He said to them, “If I tell you, you will (BW)by no means believe. 68 And if I [k]also ask you, you will by no means answer [l]Me or let Me go. 69 (BX)Hereafter the Son of Man will sit on the right hand of the power of God.”
70 Then they all said, “Are You then the Son of God?”
So He said to them, (BY)“You rightly say that I am.”
71 (BZ)And they said, “What further testimony do we need? For we have heard it ourselves from His own mouth.”
Footnotes
- Luke 22:7 Sacrificed
- Luke 22:14 NU omits twelve
- Luke 22:18 NU adds from now on
- Luke 22:31 NU omits And the Lord said
- Luke 22:37 fulfilled
- Luke 22:43 NU brackets vv. 43 and 44 as not in the original text.
- Luke 22:57 NU it
- Luke 22:60 NU, M a rooster
- Luke 22:61 NU adds today
- Luke 22:64 NU And having blindfolded Him, they asked Him
- Luke 22:68 NU omits also
- Luke 22:68 NU omits the rest of v. 68.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Scripture taken from the New King James Version®. Copyright © 1982 by Thomas Nelson. Used by permission. All rights reserved.
