Matiu 12:18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 (A)“Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn.
Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;
èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.
Matiu 17:5
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
5 (A)Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán ṣíji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”
Read full chapter
Marku 9:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Ìkùùkuu kan sì bò wọ́n, ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu náà wá wí pé: “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: Ẹ máa gbọ́ ti rẹ̀!”
Read full chapter
Luku 9:35
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
35 (A)Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
Read full chapter
Saamu 2:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:
Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
lónìí, èmi ti di baba rẹ.
Isaiah 42:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìránṣẹ́ Olúwa náà
42 (A)“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró,
àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀;
Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀
òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.