Add parallel Print Page Options

24 “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀. 25 Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli. 26 Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí. 27 Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”

28 Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,
    ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?
Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè
    sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.
29 Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,
    gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
30 Báyìí ni Olúwa wí:
“Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,
    ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀;
nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere,
    èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi
    tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”

Read full chapter