Saamu 139
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi
24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú
kan bá wà nínú mi kí ó sì
fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.