Numeri 14:18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 ‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’
Read full chapter
Nehemiah 9:17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
Read full chapter
Saamu 86:15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
Saamu 103:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Saamu 145:8
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
Jona 4:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.