Matiu 24:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín gbogbo ilé yìí ni a yóò wó lulẹ̀, kò ní sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí òmíràn, tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
Read full chapter
Matiu 27:40
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
40 (A)“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”
Read full chapter
Ìṣe àwọn Aposteli 6:14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
14 Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.”
Read full chapter
Johanu 2:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 (A)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.