Matiu 24:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ.
Read full chapter
Matiu 24:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.
Read full chapter
Esekiẹli 22:27
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
27 Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́.
Read full chapter
1 Johanu 4:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò
4 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.
Read full chapter
Johanu 10:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.