Luku 6:37-38
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Dídá ni lẹ́jọ́
37 (A)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. 38 (B)Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”
Read full chapter
Marku 4:24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
24 (A)Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Read full chapter
Romu 2:1
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run
2 (A)Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dá ni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dá ni lẹ́jọ́.
Read full chapter
Romu 14:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.